Home / Iroyin Pajawiri / Ìkéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà
ÌKéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ ÌJẹ̀ṣà

Ìkéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà

Ní ìtẹ̀síwájú orò ìwúyè Ọwá Obòkun Àdìmúlà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá Clement Adésuyì Haastrup, wọ́n ti kéde ìṣéde jákèjádò ìlú Iléṣà. Gẹ́gẹ́ bí Olóyè Àgbà Ọlálékan Fọ́lọ́runṣọ́ tí wọ́n jẹ́ Loro ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ṣe kéde, ìṣéde náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́jọ alẹ́ òní Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ kọkànlá títí di aago mẹ́fà Òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹrin (8pm of April 11 to 6am of April 12, 2025)

Kí eku ilé ó gbọ́, kó sọ fún toko o!!! Gbogbo ènìyàn pátá, Onílé àti Àlejò ni ìṣéde yìí kàn o🎤🎤🎤

Orísun ìròyìn :Ijesa News

ÌKéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ ÌJẹ̀ṣà

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

pankere

Ẹ kú ojúmọ́ Ọjọ́bọ̀ tòní o!

Àwòrán Ogbè Ìwẹ̀yìn wa tòní rè, ẹ jẹ́ kí á rántí àwọn Olùkọ́ tí wọ́n máa ń kó pankẹ́rẹ́ bí ẹni tí ń tẹ̀lé Eégún. Kí lorúkọ Olùkọ́ yín tó máa ń gbé pankẹ́rẹ́ kiri nílé ẹ̀kọ́ Ṣẹ́kọ́ńdírì tí ẹ lọ?