Home / Àṣà Oòduà / Ní Iwájú Si : Nípa Ìlànà Oba Ifá Ti Gúúsù America (South America).

Ní Iwájú Si : Nípa Ìlànà Oba Ifá Ti Gúúsù America (South America).

Àrídájú ti so wípé…
1. Àwon ènìyàn kan wà tí won ń lo orúko àti ipò Aláàfin láti fi lu àwon tí kò mò nípa Àsà yorùba ní jìbìtì ní ìlú òyìnbó.
2. Àwon babaláwo tí ó wà lábé ilé-ifá Ìjo ifá Àdìmúlà. Wón ń gbá àwon ènìyàn lórí èro ayélujàra (internet) nípa fífún won ni oyè orísirísi láì fi tó Aláàfin létí.
3. Aláàfin Oba Adeyemi, ti ń lo òfin láti ri wípé àwon afurasí oníjìbìtì wònyí San owó ìtanràn pé won fi Àsà yorùba wólè ní gbogbo àgbáyé.
4. Ààfin ti bèèrè gbàgede fún gbogbo elésìn àbáláyé láàrin ìlú kí won fi orúko sílè lábé egbé tí a mò sí Àsà òrìsà láti ri wípé wón wà ní ìbámu pèlú ìse onísèse àti láti kápá ìwà jìbìtì.
5. Orúko àwon afurasí wòn yí ni :Faniyi Awoniran Omoyemi, Ojelabi Okewole, Faleye  Ikusaanu,  Famuwagun   Oloyede, Ifayemi Olaniyan, Ifakorede Ifaloseyi, Ifadotun Fatoki, Oyasogo Ifakorede, ifasooto Ifawumi Adeyemo,  Awoniran Awotunde, Awoniran Ifamuyiwa àti béè lo.
6. Ikusaanu Faleye, Fasola Olaniyan àti Olaniyan Awoyemi nìkan ni ó ti Fara hàn ní ilé ejó ní ìyágànku Ibadan tí ó sì kun àwon tí ó pò.
7. Èsè mérin òtòtò ni a ti  kà sí won lésè Èsè òdaràn, ìfirawé, Ayédèrú àti ìwà tí ó le mú ìpalára wá fún àláfíà ìlú.
8. Abánirojó, Fasola Sunday, sàlàyé wípé olùjéjó àti àwon tí ó ń se àfarawé Aláàfin fi oyè fún ènìyàn wípé kòsí oyè kankan tí ó ńlá jé Oba ifá ti gúúsù America (south America) lórí àtòhúnrìwá kankan.
9. Àwon olùjéjó se ayédèrú ìwé-èrí oyè náà tí won sì fi irú rè fún Franciva Leoa Nobres tí wón so ní Ifatoowo Adebayo :Dasiel Guerra, Awotunde Ajisola : àti Jose Lara tí won so ni Ifakayode Falade.
10. Àwon tí a fi èsùn kan wí àwíjàre pé àwon kò jèbi èsùn tí a fi kàn wón tí ó sì jé wípé Adájó AA. Adebisi sì fún won ní béèlì egbèrún lónà ogóòrun (#100,000) tí àrídájú isé sì wà, wón sún ejó nà lo sí ojó ketàdínlógún osù kefà (July 17).
11. Olúwo ti òyó Aláàfin, Ifatoki Ojo fi àrídájú lélè wípé babaláwo kankan kò ní  àse láti fi enikéni je oyè láìní owó Aláàfin nínú

English Version
Continue after the page break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

tems

Mo setán láti kú’ – Tems

Mo setán láti kú’ – Tems Mary Fágbohùn Olorin Naijiria olugbafe eye Grammy, Temilade Openiyi, ti a mo si Tems, ti safihan pe oun setan lati doju ko saare nigba ti oun fi eya orin takasufe ti gbogbo eniyan mo kaakiri orile ede sile fun R&B. Tems wi pe oun ni igbagbo pupo ninu ara oun to bee ti oun ko bikita bi oun o ba “je nnkankan tabi da enikeni” pelu R&B. Olorin ‘Essence’ naa so pe oun kan ...