Home / Àṣà Oòduà / Ipo wo ni iwo fe wa ninu awon olowo ile Afirika?

Ipo wo ni iwo fe wa ninu awon olowo ile Afirika?

Ni owuro yii, mo fi akoko mi sile lati ka nipa aseyori Mike Adenuga, alase ati oludari ile ise ibanisoro Gbobacom. Ohun to ta mi kan ko ju iroyin tuntun nipa re eleyii to n se afihan re gege bi enikeji to lowo ju lo bayii ni ile Afirika gege bi atejade tuntun Magasiinni Forbes agbaye odun 2016. Ninu awon eniyan bi merinlelogun (24) ti Forbe se alaye won gege bi borokini olowo julo ni ile adulawo, ipo kinni si ni Dangote dimu, Adenuga se ipo keji. Femi Otedola wa nipo kerinla nigba ti Arabirin Folorunso Alakija wa ni ipo kerindinlogun.

Iwadii Forbes fihan wi pe, ohun ti Adenuga n je lere ti fo fere lati bilionu merin owo dollar ile Amerika lodun 2015 bo si billion mewaa owo dollar ninu odun 2016.

Ohun kan ti mo fe fi dayin loju ni wi pe, ki i se gbogbo eniyan to rise gidi se ni won sanwo riba fun enikan ki won to fun won nise se. Bakan naa ni ki i se gbogbo olowo ile Naijiria ni won jale tabi gba ona alumonkoroyi ki won to deni atata lawujo.

Eyin naa le ti apata dide, ke e si di bee di eniyan atata lawujo.

Aseyori eda bere lati ibi ero okan re. Ohun ti e dimu gege bi otito ni o pada royin lara bi aso. Ti e ba gbagbo wi pe e pada doke, mo fi n dayin loju wi pe, ohun to seese ni. Nitori ero okan yin, igbagbo yin, bope-boya yoo pada royin lara bi aso. Ewu wa ninu igbagbo yin wi pe, eniyan ko le debi giga laise se wi pe o gba ona alumonkoroyi.

Ti e ba ni iru ero bayii lokan, ohun ti e n so fun ara yin ni wi pe, e ko peye to lati se asela laye. Iru ero wo le dimu nipa igbe aye yin? Kini igbagbo yin nipa ojo ola yin? Oni le koro bi ewuro, sugbon e fi igbagbo yin sinu ola. E ma so ireti aseyori yin nu. E si ma fi gbogbo igba ro ire nipa igbe aye yin. E ma gbagbe ohun ti mo so saaju, orisii ero yowu ki e ni lokan, bope-boya, ero okan yin yoo pada royin lara bi aso. Olayemi Olatilewa ni oruko mi, ilu Naija olokiki ti n san fun wara ati oyin lemi n ja fun lojo gbogbo. E ku ikale!

http://www.olayemioniroyin.com/2016/03/ipo-wo-ni-iwo-fe-wa-ninu-awon-olowo-ile.html

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*