Home / Àṣà Oòduà / Èsì àyẹ̀wò tuntun Nàìjíríà fihàn pé “313” èèyàn ti gbàlejò Kofi 19 …àjọ NCDC

Èsì àyẹ̀wò tuntun Nàìjíríà fihàn pé “313” èèyàn ti gbàlejò Kofi 19 …àjọ NCDC

Èsì àyẹ̀wò tuntun Nàìjíríà fihàn pé “313” èèyàn ti gbàlejò Kofi 19 …àjọ NCDC

À fi kí á bẹ Ọlọ́run kó bá wa dásí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ajániláyà pàtì yìí, bí àwọn tó ní kòrónáfairọ̀ọ̀sì ní Nàìjíríà ti ń peléke sí i báyìí,lẹ́yìn tí àjọ NCDC tún kéde okòólélọ́ọ̀dúnrún dín méje èèyàn tí èsì àyẹ̀wò wọn sẹ̀sẹ̀ jáde.

Ní báyìí, èèyàn ẹgbẹ̀rún méje, àti . òjìlélẹ́gbẹ̀rin dínkan (7839) ni àkọsílẹ̀ wà pé ó ti ní àrùn náà ní Nàìjíríà.

Àkójọpọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tí èsì tuntun náà ti wá nìyí.

Àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ arun l’órílẹ̀èdè Nàìjíríà, NCDC, kéde pé ènìyàn igba àti márùndínláádọ́rin ni àyẹ̀wò fihàn pé ó tún ní àrùn ni apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì Naijiria.

Nínú èsì àyẹ̀wò náà, ìpínlẹ̀ Èkó ní èèyàn mẹ́taleláàdóje, Ọ̀yọ́ ní mẹtàlélọ́gbọ̀n, Edo sì ní méjìdínlọ́gọbn.

àwọn tó ti ní l’órílẹ̀èdè Nàìjíríà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́rìndinlọ́ggbọ̀n (7526).

Ẹgbẹ̀rún méjì àti mẹ́rìnléláàdọ́sàn (2174), ti rí ìwòsàn, okòólérúgba lé kan (221) sì ti kú.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

seun kuti

Orí kó Seun Kuti yọ kúrò lọ́wọ́ ikú ní yàrá ìgbàlejò US

Mary Fágbohùn Olórin Afrobeat Seun Kuti ti fi ìrírí ibanuje ọkàn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà han nígbà tí ọta ibọn kan gúnlẹ̀ lójú fèrèsé yàrá igbalejo rẹ̀. O salaye ibapade to ba ni lẹru naa lori oju-iwe Instagram rẹ, o fi fidio ferese ti ọta ibọn naa bajẹ ati iho re han. Seun, ẹni ti o ṣalaye iyalẹnu, beere iwoye ti aabo ni Amẹrika. Ninu fonran naa, Seun Kuti sọ pe oun wa ninu yara igbalejo, ti oun n sinmi, ...