Home / Àṣà Oòduà / Ile ejo ti ran Jimoh lewon leyin to fi ehin ja ori oyan asewo niluu Ibadan

Ile ejo ti ran Jimoh lewon leyin to fi ehin ja ori oyan asewo niluu Ibadan

Ile ejo ti ran Jimoh lewon leyin to fi ehin ja ori oyan asewo niluu Ibadan

Orisun
Oniroyin: Twitter

Ile ejo Majisireeti ti n jokoo niluu Ibadan ti ran Ogbeni Sunday Jimoh lewon bayii leyin igba to fi ehin ja ori oyan arabirin Meseheno Asukwo niluu Ibadan. Ni nnkan bi ago mejo ale Ojoru to ko ja yii (21/10/15) ni Sunday, eni odun mokandinlogun (19) lo je igbadun ara re ni ile asewo kan to wa ni agbegbe Ekotedo niluu Ibadan. Gege bi iwadii Iroyin Owuro, igba ti Sunday je dodo omoge tan, ko di wi pe ko sanwo asewo lo ba bere si ni so sitoori repete fun Meseheno.

Meseheno omo yibo ba fabinu yo. Bee lo n pariwo pelu adamodi geesi ati ede yibo wi pe ki Sunday o sanwo oja to ra ni kiakia. Meseheno ti inagije re n je Angel ba gbinyanju lati towo bo inu apo Sunday nigba to ko ti o dalohun boro. Ibi ija ti gbe bere ni yii, ti Sunday n fi gbogbo ara ja bi eni jagun Kiriji.

Nibi ija yii lo ti fehin ja ori oyan Angel omo pupa roboto, to si tun fehin kola gomba si gbogbo oju re pata.

Awon eniyan sare gbe Angel lo si ile iwosan nigba ti won dana iya fun Sunday ko to di wi pe won fa a le awon olopaa lowo. Enikeni ko le so fun wa nipa ibi ti Sunday n gbe abi iru ise ti n se gan-an. Sugbon iwadii fi ye wa pe igba akoko ko ni yii ti omokunrin naa ti maa wa naja awon asewo.

Lojo keji ti isele yii waye, adajo agba Majisireeti, Arabirin Munirat Giwa-Babalola ti n jokoo nile ejo Majisireeti Iyaganku niluu Ibadan ti dajo ewon osu mefa (6) fun Sunday nigba ti ile ejo fidi re mule wi pe bobo naa jebi awon esun ti won fi kan an.

Orisun
Oniroyin: Twitter

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo