Orí kó ènìyàn márùn-ún yọ lọ́wọ́ coronavirus l’Ekoo
Ìròyìn láti ọwọ́ Yínká Àlàbí
Alaisan marun-un ninu awon ti arun buruku covid-19 ti n ba finra lati bii ose meloo kan seyin gba idande. Yoruba bo “won ni alaare ko ki n ra si inu yara, bi o segun aisan, yoo fi ese ara re rin jade, bi o ba si yiwo naa, won a gbe oku re jade”.
Eyi lo sele si awon marun-un ti arun coronavirus ti n ba poo, ti won si segun arun naa, nitori pe gbogbo ayewo ti won se fun won lera-lera si gbee pe aisan naa ko si lara won mo.
Minisita eto ilera Dokita Osagie Ehanire ati ajo NCDC se tun n parowo si gbogbo omo Naijiria, won ni arun naa ko tii ni oogun kan gbogi nipa idi eyi, ki awon eniyan so ewe agbeje mowo. Ki onikaluku si gbe inu ile re gege bi gbogbo eka ijoba se n forere.