Home / Àṣà Oòduà / Seyi Makinde di gómìnà kẹ́ta tó kó àrùn Covid-19

Seyi Makinde di gómìnà kẹ́ta tó kó àrùn Covid-19

Oni ogbon ojo, osu keta ni ayewo gomina ipinle Oyo, Alagba Seyi Makinde jade, ti ayewo naa si gbee pe o ni arun naa. Oun ni o maa je eleeketa gomina ni orileede yii ti ayewo fihan pe won ni arun kokoro naa.


Gomina ipinle Bauchi, Bala Mohammmed ni o koko ni, ki ayewo to gbe ti gomina ipinle Kaduna , Nazir El-Rufai jade. Eyi lo mu ki gbogbo eka ijoba maa pariwo ki onile ko gbele nitori ajakale arun naa.

Arun naa ko mo olowo, bee ni ko mo talaka. Arun naa ko ni aponle fon egbe oselu to n se ijoba lowo de bi to maa ni fun egbe oselu ti ko se ijoba rara. Bi ojo ni arun naa se n rin, “eni ti eji re ri ni eji n pa”.

Seyi Makinde di gómìnà kẹ́ta tó kó àrùn Covid-19
Ìròyìn láti ọwọ́ Yínká Àlàbí

About ayangalu

x

Check Also

ÌKéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ ÌJẹ̀ṣà

Ìkéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà

Ní ìtẹ̀síwájú orò ìwúyè Ọwá Obòkun Àdìmúlà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá Clement Adésuyì Haastrup, wọ́n ti kéde ìṣéde jákèjádò ìlú Iléṣà. Gẹ́gẹ́ bí Olóyè Àgbà Ọlálékan Fọ́lọ́runṣọ́ tí wọ́n jẹ́ Loro ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ṣe kéde, ìṣéde náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́jọ alẹ́ òní Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ kọkànlá títí di aago mẹ́fà Òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹrin (8pm of April 11 to 6am of April 12, 2025) Kí eku ilé ó gbọ́, kó sọ fún toko o!!! Gbogbo ènìyàn ...