Arápájà di Igbákejì Alága ẹgbẹ́ PDP níhà Gúúsù Orílẹ̀ yìí
Ọrẹ Akínṣọlá
Ṣé bóṣe wu Ọlọ́run Ọba ní-ín sọlá, èèyàn tó bá wù Ú ní-Ìn ṣe lógo.
Igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbààa kan, Ọ̀gbẹ́ni Taofeek Arapaja, ti jáwé olúbori sípò Ìgbákejì Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní Gúúsù ilẹ́ wa, ó sì fẹ̀yìn alátakò rẹ̀ tóun náà jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀sun tẹ́lẹ̀rí, Ọmọọba Ọlágúnsóyè Oyinlọlá, janlẹ̀.
Iṣẹlẹ yii waye lowurọ ọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa yii, lasiko ti wọn n ka abajade ibo tawọn aṣoju to pesẹ sibi apero apapọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ọhun di, lati mọ ẹni to maa wa nipo igbakeji alaga ẹgbẹ lagbegbe Guusu Naijiria.
Ṣaaju ni awuyewuye ti wa pe ki ẹnikan ninu awọn ondije fun ipo Igbakeji alaga naa juwọ silẹ fun ẹnikeji, ko le dọgba pẹlu eto ti ẹgbẹ PDP ṣe lori awọn ipo ijoye ẹgbẹ yooku, leyii ti ko si alatako kankan, ayafi ipo Igbakeji alaga Ariwa.
Ṣugbọn ko sẹni to juwọ silẹ laarin Arapaja, ti Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ jẹ igi lẹyin ọgba fun gbagbaagba, ati Ọmọọba Oyinlọla ti gbogbo eeyan bọwọ fun bii ọkan lara awọn agba ẹgbẹ PDP. Eyi lo mu kọrọ naa di didibo le lori.
Lẹyin idibo, gẹgẹ bi Gomina Ahmadu Umaru Fintiri tipinlẹ Adamawa ṣe kede abajade rẹ, Arapaja ni ibo ẹgbẹrun meji o le mẹrin (2004), nigba ti Oyinlọla ni ibo ẹẹdẹgbẹrin o le marun-un (705), ninu ẹgbẹrun mẹta aabọ ati mọkanla (3511) aṣoju ti wọn pesẹ sibi eto naa.
Aropọ ibo marunlelọgọjọ (165) ni wọn ni ko wulo, wọn da a nu bii omi iṣanwọ ni, awọn aṣoju ojilelẹgbẹta din mẹta (637) ni wọn ko dibo lasiko idije ọhun.
Pẹlu eyi, Taofeek Arapaja ni Igbakeji alaga ẹgbẹ PDP niha Guusu ilẹ wa.