Home / Aarin Buzi / 😳 Mercy Johnson Kìlọ̀ Gidi: “Ọ̀rọ̀ Ọkọ àti Aya, Ẹ Jẹ́ Kí Wọ́n Yanjú Rẹ̀ Fúnra Wọn!”
Mercy Johnson Kìlọ̀ Gidi

😳 Mercy Johnson Kìlọ̀ Gidi: “Ọ̀rọ̀ Ọkọ àti Aya, Ẹ Jẹ́ Kí Wọ́n Yanjú Rẹ̀ Fúnra Wọn!”

“Ọ̀rọ̀ ọkọ àti aya tàbí ohunkóhun tó bá kan ìfẹ́, ẹ má ṣe dá sí i, ẹ má ṣe gbìmọ̀, ẹ má sì ṣe ran wọn lọ́wọ́. Wọ́n ti lò mí láti yanju ọ̀rọ̀ wọn.” 😩😂

Mercy Johnson, ẹni tí Regina Daniels ń pè ní Iya Isale(Godmother) rẹ̀, ti dá àwọn ènìyàn lójú lórí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí tí ó ń tàn káàkiri lórí social media.

Àwọn olólùfẹ́ Regina ti ń so ọ̀rọ̀ tí Mercy so yìí pọ̀ mọ́ àwọn ìròyìn àti àhesọ tó ń lọ káàkiri nípa Regina Daniels àti Ned Nwoko, pàápàá jù lọ lẹ́yìn àwọn ìròyìn pé àwọn méjèèjì lè ti tún pada sinu igbeyawo wọn.

Ṣé Mercy ń sọ̀rọ̀ láti inú ìrírí tirẹ̀ ni? 👀 Tàbí ó kan ń fún gbogbo wa ní ìmọ̀ràn pé “ọ̀rọ̀ ọkọ àti aya, ẹ jẹ́ kí wọn yanjú rẹ̀ fúnra wọn”? 😂😂

Ẹ̀yin náà, kí le rò pé òrò Mercy túmọ̀ sí gan-an? 👇🏽

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

mko

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó f’ọ́lé e MKO Abiola

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó f’ọ́lé e MKO Abiola À ṣẹ kò sééyan táyé ò lé bá ṣọ̀tá, ó tún hàn pé wọ́n le bínú òkú ọ̀run , yàtọ̀ sèèyan tí wọ́n jọ ń wà láyé. À bí kín ní ká tí pé tàwọn kọ̀lọ̀rànsí t’ọ́wọ́Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ báyìí pé wọ́n digunjalè sọsẹ́ nílé olóògbé Olóyè Moshood Abíọ́lá tó wà ní Ìkẹjà nílùú Èkó níbi tí wọ́n ti jí nǹkan tó tó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù lọ. Abíọ́lá ló jáwé olúborí ...