Home / Àṣà Oòduà / Àfàìmọ̀ Kí Coronavirus Má Dà Bí I Ti China Tabi Italy- Mínísítà Kìlọ̀

Àfàìmọ̀ Kí Coronavirus Má Dà Bí I Ti China Tabi Italy- Mínísítà Kìlọ̀

Ẹni mẹ́rin mì ìn kó àrùn apinni ní mímí èèmii coronavirus ní Nàìjíríà,àfàmọ̀ kò mọ́ dà bí i ti China,l Italy— Mínísítà kìlọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìgbọrọ̀ sàn ju ẹbọ rúrú fún ẹni tó bá fẹ́ gbọ́ ni o.
Ó ti di ogójì èèyàn tó ti lùgbàdì àrùn coronavirus báyìí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹ́yìn tí àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC kéde àwọn mẹ́rin míì tó ti ní àìsàn náà lálẹ́ ọjọ́ Ajé.

Àjọ NCDC ṣàlàyé pé mẹ́ta nínú àwọn èèyàn wá láti ìpínlẹ̀ Èkó nígbà tí ẹyọ kàn tó kù wá láti olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Abuja.

NCDC ní àwọn méjì nínú wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ rìnrìn àjò dé láti òkè òkun ni.

Gẹ́gẹ́ bí àlàyé àjọ NCDC lójú òpó Twitter rẹ̀, èèyàn méjì nínú àwọn ogójì èèyàn tó lùgbàdì àrùn Covid-19 ní Nàìjíríà ti kúrò nílé ìwòsàn.

Èèyàn kan ti dèrò ọ̀run nínú àwọn tó lárùn náà ní Nàìjíríà, ọjọ́ Ajé ni ọkùnrin náà ẹni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rin kú.

Ohun tí a gbọ́ ni pé ọkùnrin ti ní àrùn ìtọ̀ ṣúgà àti àrùn jẹjẹrẹ lára tẹ́lẹ̀ kí ó tó lùgbàdì coronavirus.

Ní báyìí, èèyàn méjìdínlọ́gọbọ̀n ló wá láti ìpínlẹ̀ Èkó nínú ogójì tó lárùn náà ní Nàìjíríà, méje
Èèyàn méjì wá láti ìpínlẹ̀ Ogun, nígbà tí ìpínlẹ̀ Èkìtì, Oyo àti Edo ni ẹyọ kọ̀ọ̀kan.

Ẹ̀wẹ̀, mínísítà fún ètò ìlera, Dókítà Osagie Ehanire ti sọ pé àfàìmọ̀ kí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà náà ó má dàbí ti orílẹ̀-èdè China àti Italy lórí bí ọ̀rọ̀ coronavirus ṣe ń lọ yìí.

Mínísítà ní ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà tó ní àrùn coronavirus ni wọ́n ń déjú mọ́lé, dípò kí wọ́n jáde fún ìtọ́jú kí àrùn náà má ba à ran àwọn mìíràn.

About ayangalu

One comment

  1. Ọlọ́hun ò ní jẹ́

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo