Home / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Ose Meji/ Ose Olubadan

Odu Ifa Ose Meji/ Ose Olubadan

|   |
| | | |
|    |
| | | |

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tun ku orire osu tuntun to tun soju emin wa o, eledumare yio muwa bori gbogbo isoro aye ati torun to doju kowa ninu osu tuntun yi o ase.
Odu ifa OSE MEJI/OSE OLUBADAN lo gate laaro yi, ifa yi gba akapo ti odu ifa yi ba jade si niyanju wipe ki o rubo ki o baa le bori gbogbo Ogun to doju ko, ki Ogun aye ati torun ma baa bori re mole o.
Ifa naa ki bayi wipe:
Irin borogidi borogidi ni alagbede fi nbowu a difa fun eji ose eyiti yio segun laye ti yio si tun segun lode orun, won ni ki o karale ebo ni ki o wa se, (obi meji………ati ewe ayajo ifa) eji ose kabomora o rubo won se sise ifa fun bi eji ose se segun laye to si segun lode orun niyen o, eji ose wa njo o nyo o nyin awo awon awo re nyin ifa, ifa nyin eledumare, oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa, nje eji ose ma de o omo abìségun wara.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ao se gbogbo Ogun aye ati tode orun to doju kowa o, Ogun orun koni muwa lo sorun ojiji beeni Ogun aye koni bori wa mole, ao di asegun loni o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version:

continue after the page break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

“Ta Ní Ó Wà Kí Ayé Tó Wà? Ìtàn Àkọ́kọ́ Ìṣẹ̀dá Gẹ́gẹ́ Bí Ifá Ṣe Sọ Ó.”

Kò sí ohun ẹlẹ́mìí kankan láyé awo ilé Ayé ni ọ̀run àkọ́kọ́, ohun tí ó so kàrà tí kò sọ̀kalẹ̀, awo òde Ọ̀run ni ó ń pè é, gbogbo rẹ̀ jẹ́ òfìfo lásán, òfo pónbele, láìní ìpìlẹ̀, láìní ẹ̀dá kankan, Awo àárín gbùn-gbùn òde ni ó wí i, A dífá fún Ayé àti fún Ọ̀run, nínú ìkarawun ìgbín méjì tí ó ṣófo, kò sí ẹyẹ, kò sí ẹ̀mí tí ń gbé inú wọn, ìpìlẹ̀ kò tí ì sí, afẹ́fẹ́ kò ...