Home / Àṣà Oòduà / Ìtànkálẹ̀ Àrùn Coronavirus Nílẹ̀ Amerika Ti Ju Ti Italy Àti China Lọ!

Ìtànkálẹ̀ Àrùn Coronavirus Nílẹ̀ Amerika Ti Ju Ti Italy Àti China Lọ!

Ìtànkálẹ̀ àrùn Coronavirus nílẹ̀ Amerika ti ju ti Italy àti China lọ!

Ìlẹ̀ Amẹ́ríkà mà ti gba ipò kínní gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí ìtànkálẹ̀ Coronavirus ti pọ̀jù lọ l’ágbàáyé pẹ̀lú ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínláádọ́rún tó ti ní àrùn náà.

Àkọsílẹ̀ fihàn pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti borí China tó ni ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin (81,782) àti Italy tó ní ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin(80,589) tó ní àrùn náà.

Àmọ́ iye àwọn ènìyàn tó ti kú ní orílẹ̀-èdè China ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́ta (3,291) àti ti Italy ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́jọ (8,215)pọ̀ ju ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan lọ (1,300).

Ìtànkálẹ̀ àrùn yìí peléke sí i lẹ́yìn tí Ààrẹ Donald Trump sọ pé ó dá òun lójú pé orílẹ̀-èdè náà yóó padà sí ipò láìpẹ́.

Ààrẹ Donald Trump lásìkò tó ń f’èsì sí ọ̀rọ̀ náà ní idi tí nọ́ńbà àwọn tó ní àrùn náà fi peléke sí i ni pé ,àwọn ń se àyẹwò fún àwọn ènìyàn lójú méjéèjì ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀.

Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Mike Pence sọ wí pé ẹgbẹgbẹ̀rún ilé ìwòsàn àyẹwò ló ti wà ní gbogbo Ìpínlẹ̀ àádọ́ta tó wà lórílẹ̀-èdè náà.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé. Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì ...