Home / Àṣà Oòduà / Àwọn Fíìmù Òde Òní Ń Kọ́mọ Lólè Àti Ọ̀pọ̀ Ìwà Burúkú – Iyabo Ogunsola

Àwọn Fíìmù Òde Òní Ń Kọ́mọ Lólè Àti Ọ̀pọ̀ Ìwà Burúkú – Iyabo Ogunsola

Àwọn fíìmù òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ẹgbẹ́ burúkú ba ìwà rere jẹ́.

Ajíyìnrere Felicia Iyabode Ogunsola tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Efúnsetán Aníwúrà, Ìyálọ́de ìlú Ìbàdàn nínú eré, ti kìlọ̀ fáwọn òṣèré tíátà láti dẹ́kun àṣà ṣíṣíra sílẹ̀ nínú fíímù.

Efúnsetán ní àṣà burúkú gbáà ni.
Ó ṣàlàyé pé kìí ṣe ohun tó dára kí àṣírí ọyàn máa hàn síta,iṣẹ́ Èṣù ni.

Ó fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá nígbà tí òun fi ń ṣeré lábẹ́ ògbóǹtarìgì òṣèré, olóògbé Iṣhola Ogunsola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Isho Pepper.

Iyabode Ogunsola ní àṣà àìbìkítà, àti àìlójútì gbá à ni.
Ó ní àṣà àwọn òyìnbó ni àwọn òṣèré òde òní ti gbé wọ eré tíátà Yorùbá.

Àgbà òṣèré náà ní àṣà kí á máa yìnbọn pò pò pò nínú fíímù ló kọ́ àwọn ọmọ lólè láyé òde òní, dípò kí àwọn ọmọdé máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ níbẹ̀.

Ó rọ ọ̀pọ̀ òṣèré tí wọn kò tíì lọ kẹ́kọ́ọ̀ eré tíátà ṣíṣe níbì kankan pé kí wọ́n yára tètè lọ se bẹ́ẹ̀ nítorí kò sí òṣèré kan tí kò kẹ́kọ́ọ̀ lábẹ́ ẹnìkan nígbà tàwọn náà.

About ayangalu

x

Check Also

ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé. Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì ...