Home / Àṣà Oòduà / Mo ti pàṣẹ fún àjọ DSS láti tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́….Abubakar Malami

Mo ti pàṣẹ fún àjọ DSS láti tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́….Abubakar Malami

Mo ti pàṣẹ fún àjọ DSS láti tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́….Abubakar Malami

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ ti pàṣẹ pé kí wọ́n tú olùbádámọràn lóri ètò ààbò Sambo Dasuki àti agbétẹrù Revolution Now Omoyele Sowore silẹ̀ nínú àhámọ́.

Mínísítà fún ìdájọ́ àti agbẹjọ́rò Ìjọba àpapọ̀ Abubakar Malami ló kéde ọ̀rọ̀ náà nínú àtẹjáde kan lọ́sàn tí wọ́n fi síta lọ́jọ́ ìṣẹ́gun.

Malami ní Ìjọba gbé ìgbésẹ̀ náà nítorí ìdájọ́ tí ilé ẹjọ dá àwọn méjéèjì.

Ó rọ àwọn méjéèjì láti dúró ti àwọn nǹkan tí ó rọ̀ mọ́ gbígba òní dúró o wọ́n, kí wọ́n sì dẹ́kun láti hu ìwà tó le da omi àlàáfíà àti ètò àbo ilú rú tabi èyí tí yóó lòdì sí ìgbẹ́jọ́ wọ́n nílé
ẹjọ́.

Malami ní ìgbẹ́sẹ̀ náà kò sèyìn ẹ̀ka òfin ọdún 1999 ní pé, àwọn ní láti fún Sambo Dasuki ní òmìnira gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn àti onídùúró Sowore tí Ilé ẹjọ́ gbà. ” mo ti pàṣẹ fún àwọn àjọ ọ̀tẹ̀lẹ̀múyẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́ tó tú Sowore sílẹ̀

iroyinowuro

About ayangalu

x

Check Also

seun kuti

Orí kó Seun Kuti yọ kúrò lọ́wọ́ ikú ní yàrá ìgbàlejò US

Mary Fágbohùn Olórin Afrobeat Seun Kuti ti fi ìrírí ibanuje ọkàn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà han nígbà tí ọta ibọn kan gúnlẹ̀ lójú fèrèsé yàrá igbalejo rẹ̀. O salaye ibapade to ba ni lẹru naa lori oju-iwe Instagram rẹ, o fi fidio ferese ti ọta ibọn naa bajẹ ati iho re han. Seun, ẹni ti o ṣalaye iyalẹnu, beere iwoye ti aabo ni Amẹrika. Ninu fonran naa, Seun Kuti sọ pe oun wa ninu yara igbalejo, ti oun n sinmi, ...