Home / Àṣà Oòduà / Ilé ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn yọ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomhole nípò

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn yọ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomhole nípò

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn yọ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomhole nípò–

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti ilú Àbújá ti yẹ àga mọ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Adams Oshiomhole nídìí

Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́tà ti adájọ́ Eunice Onyemanam sójú fún ni wọ́n fẹnu kò láti jan idájọ́ tí ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ dá tẹ́lẹ̀ lóntẹ̀

Sáájú ni Oshiomhole ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ tí àdájọ Abubakar Yahaya sì dájọ pé kí ìdájọ́ náà dúró náà kí ó ṣì máa ṣe alága lọ́ títí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yóò ṣe fìdímúlẹ̀.

Adájọ́ Onyemanam tó dárí ẹjọ́ tó wáyé l’ọ́jọ́ ìṣègùn ló dá ẹjọ́ náà ló fídí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kékeré tó yọ Adams Oshiohmole gẹ́gẹ́ bí alágá nínú ọṣù kẹta ọdún yìí ṣe nǹkan tó yẹ àti pé, ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn tí Oshiomhole pè kò fìdì múlẹ̀.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé. Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì ...